Page:PeterRabbit1910.djvu/62

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Pététù kò dẹ́kun eré sísá tàbí kí ó wo ẹ̀yìn rárá títí ó fi dé ilé wọn ní ibi igi-fírí.

Ó ti rẹ̀ẹ́ débi wípé ó réwó sí oríi iyanrìn alálùbáríkà ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ inú ihò-ehoro wọn tí ó sì gbá ojú méjèèjì mọ́rí. Ìyá rẹ̀ ń dáná lọ́wọ́ nígbà tí ó wọlé; ǹkan tí ó fi àwọn aṣọ rẹ̀ ṣe sì ṣe ìyá rẹ̀ ní kàyéfì. Ójẹ́ ìgbà ìkejì tí yíò sọ kóòtù kékeré àti àwọn ẹsẹ̀ bàtà rẹ̀ méjèèjì nù ní ọjọ́ mélòó kan!