Page:PeterRabbit1910.djvu/58

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Pétérù yọ́ kẹ́lẹ́ bọ́lẹ̀ kúrò nínú kẹ̀kẹ́-akẹ́rù náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sáré lọ pẹ̀lú gbogbo okun rẹ̀, gba ọ̀nà tóóró lẹ́yìn àwọn igi aduigbo.

Ọ̀gbẹ́ni McGregor kó fìrí rẹ̀ bí ó ti ńsálọ, ṣùgbọ́n Pétérù kò rán rárá. Wéré ló kó sábẹ́ẹ ilẹ̀kùn ńláa ọgbà bọ́ sí ta, tí ó ṣoríbọ́ pátápátá nínú ìgbẹ́ tí óuń bẹ níta a ọgbà náà.