Page:PeterRabbit1910.djvu/54

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


LẸ́YÌN èyí ni ó tiraka láti wá ọ̀nà gba inú ọgbà nípa títọ̀ọ́lọ réré, sùgbọ́n bí ó ti ń tọ ọ̀nà náà ló ni ó ún rúu lójú si. Wàyìí, ó jásí ibi omi okudu tí Ọ̀gbẹ́ni McGregor ti ńma pọn omi sí inú àwọn agolo omi rẹ̀. Ológbò funfun kan ń ṣọ́ ẹja aláwọ̀-yẹ́lò kan, ó baa pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, sùgbọ́n lóòrèkóòrè ìrù rẹ̀ a sì mì bíi wípé ó dá ní ẹ̀mi tirẹ̀ lọ́ọ̀tọ́. Pétérù wòye wípé ohun tí ó dára jùlọ ni kí òhun fi alayé yẹn sílẹ̀ láì sọ̀rọ̀ síi rárá; ó ti gbọ́ onírúurú ìtàn nípa àwọn Ológbò láti ẹnu ará-ilé rẹ̀, arákùnrin Bẹnjí Búnnì.