Page:PeterRabbit1910.djvu/53

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Ó ṣe alábápàdé ilẹ̀kùn lára ògiri kan; sùgbọ́n títì pa ni ilẹ̀kùn náà wà, kò sì sí àyè lábẹ́ rẹ̀ fún omo ehoro tí ó sanra láti fún ara rẹ̀ gbà kọjá.

Arábìnrin Asín kan ń sáré lọọ bọ̀ọ̀ lóri pẹ̀tésì olókúta tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ilẹ̀kùn náà, bẹ́ẹ̀ sìni óún kó àwọn ẹ̀wà onírúurú lọ fún àwọn ìdílé rẹ̀ nínu ijù. Pétérù bií ní ọ̀nà dé ẹnu ilẹ̀kùn ńlá ọgbà, sùgbọ́n arábìnrin náà fi ẹ̀wà ńlá kan há ẹnu dé bi wípé kò leè dáa lóhùn rárá. Ó kàn fi orí júwe fún ni. Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ sì ní sun ẹkún.