Page:PeterRabbit1910.djvu/50

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


PÉTÉRÙ jòkó láti sinmi; ó ti rẹ̀ẹ́ gidigidi níṣe ni ara rẹ̀ sì ń gbọ̀n lọ́wọ́ ẹ̀rù bíbà, ọ̀nà tí yíò sì gbà kò yée mọ́ rárá. Bẹ́ẹ̀ni ara rẹ̀ ńrin fún omi nípa bí ó ti ṣe jòkó sínu agolo tí ó kósí.

Ní ìgbà tí ó ṣe díẹ̀ ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn kiri, tí ó sì ń lọ wúyẹ́ - wúyẹ́ - láì kánjú rárá, bẹ́ẹ̀ sìni ló ún wobí wọ̀hún.