Page:PeterRabbit1910.djvu/49

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Ó sì gbìyànjú láti tẹẹ Pétérù pa mọ́lẹ̀, tí ó yára fò gba ojú fèrèsé bọ́ síta, tí ó sì fi ara wọ́ ńkan ọ̀gbìn mẹ́ta ṣubú nípa bẹ́ẹ̀. Ojú fèrèsé náà kéré fún Ọ̀gbẹ́ni McGregor láti gbà kọjá, ó sì ti sún láti máa sá tẹ̀le Pétérù kiri. Ni ó bá padà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.