Page:PeterRabbit1910.djvu/46

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Ò dá Ọ̀gbẹ́ni McGregor lójú wípé Pétérù ń bẹ ninu iyàrá-ìkórinṣẹ́pamọ́ṣí náà, ó sì ṣeéṣe kí ó sá pamọ́ sí abẹ́ kòkò-òdòdó kan níbẹ̀. Ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ní yí wọn dà díẹ̀díẹ̀, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sì ń wo abẹ́ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Lọ́gán ni Pétérù sín - 'Sínhìn!' Ni Ọ̀gbẹ́ni McGregor bá gbá tẹ̀le láì fi àkókò sòfò rárá.