Page:PeterRabbit1910.djvu/41

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Bẹ́ẹ̀ni Pétérù fira rẹ̀ fún ìsubú yìí, tí ó sì ńda ẹkún lójú bí òjò; ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ Ologoṣẹ tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ fun gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀, wọ́n sì fò wá ba ní ọ̀yàyà, wọ́n gbáà ní ìyànjú kí ó tara ṣàṣà dìde, kí ò má gba ìsubú náà ní kádàrá.