Page:PeterRabbit1910.djvu/38

From Wikiguage
Jump to: navigation, search
This page has been validated


Lẹ́yìn tí ó nuu àwọn bàtà rẹ̀ tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sáré, ó sì yára ju ìgbà tí kò wọ bàtà lọ, dé bi wípé ó dá mi lójú pé kì bá jápa yányán bí ò jẹ́ wípé ó sèèsì já sáwọ̀n gúsíbẹrì, èyí tí ó sì kọ́ọ láwọn bọ́tìnì ńlá ńlá tí ó ńbẹ ní ara kóòtù kékeré tí ó wọ̀. Kóòtù náà jẹ́ aláwọ̀ búlúù́́ tí ó sì ní bọ́tìnì idẹ, aṣọ tuntun nii.